Tèmi Nì Tèmi

Brymo

Ife mi dari jinmin
Omo de nse mi
Afarawe o se temiKa da duro ni mo wari
Moti so tele tele ri
Igboro o ma rerin ri
Ijakadi lomu nise
Ka ro′nri o b'opo sise

Bi nba fa a, won l′ole
Bi nba tule, won lo ro
Bi nduro won ma mu'ere
Bi nba sa won ni mo kere
Aba lo aba bo
Bo wunwon kan'para won
Owun ani lan nani
Temi ni temi

Awelewa f′ori jinmin
Mo lokaaka kin to debi
Riro mede o se temi
Nibi lile lan b′okunrin
Ife re sa loduro timi
Odudu ofunfun o pupa
Ife re sa lon'munu tumi
Ninu eerun at′ojo at'ailera

Bi nba fa a, won l′ole
Bi nba tule, won lo ro
Bi nduro won ma mu'ere
Bi nba sa won ni mo kere
Aba lo aba bo
Bo wunwon kan′para won
Owun ani lan nani
Temi ni temi

Aba lo aba bo
Temi lo je la'le oni o
Gbogbo igba ti o oba lo
Mo mo o pada wa